- mf Bawo ni awọn èwe wa,
Y’o ti ma ṣọra wọn?
Bikoṣe “nipa ‘kiyesi,
Gẹgẹ bi ọ̀rọ Rẹ”.
- ‘Gba ọ̀rọ na wọ̀ ‘nu ọkàn,
A tan imọlẹ ka;
Ọ̀rọ na kọ òpe l’ ọgbọn,
At’ imọ̀ Ọlọrun.
- f Orùn ni, imọlẹ wa ni,
Amọna wa l’ọ̀sán;
Fitila ti nfọnahan wa,
Ninu ewu oru.
- Ọrọ Rẹ, otọ ni titi,
Mimọ́ ni gbogbo rẹ̀;
Amọn gb l’ ọjọ ewe,
Ọpa l’ọjọ ogbó. Amin.