- f Oluwa ọjọ isimi,
Gbọ́ ti wa, pẹlu wa loni;
Awa pade fun adura,
A fẹ gb’ ọ̀rọ t’ o fi fun wa,
- Isimi t’ aiye yi rọrùn,
Ṣugbọn isimi t’ ọhun dùn;
Lala ọkan wa fẹ ‘jọ na,
T’ a o simi lailẹṣẹ dá.
- mf Kò si ‘jà, kò si ‘dagirì,
Kò s’ aniyan bi t’aiye yi
T’ y’o dapọ mọ ikọrin wa,
T’ o nt’ ete aikù jade wá.
- Bẹ̀re, ọjọ t’ a ti nreti,
Afẹmọ́jù rẹ l’ a fẹ ri;
A fẹ yọ lọna ìṣẹ́ yi
mf K’ a sùn n’ ikú, k’ a jí l’ ayọ. Amin.