- mf Bibeli mimó t’ọrun,
Ọwọn isura, t’ emi !
‘Wọ ti nwi bi mo ti ri,
‘Wọ ti nsọ bi mo ti wà.
- p ‘Wọ nkọ mi, bi mo ṣinà,
cr ‘Wọ nf’ ifẹ Oluwa hàn;
mf ‘Wọ l’ o si ntọ́ ẹsẹ mi,
‘Wọ l’o ndare, at’ ẹbi/
- f ‘Wọ n’ ima tù wa ninu,
Ninu wahala aiye;
cr ‘Wọ nkọ ni, nipa ‘gbagbọ
Pe, a lè ṣẹgun ikú.
- ‘Wọ l’ o nsọ t’ ayọ ti mbọ
At’ iparun ẹlẹṣẹ;
Bibeli mimọ́ t’ọrun,
Ọwọn iṣura, t’ emi. Amin.