- f Mo f’iyin ailopin
Fun Ọlọrun Baba,
Fun ore aiye mi,
At’ ireti t’ọrun.
O ran Ọmọ Rẹ̀ ayanfẹ,
p Lati ku fun ẹṣẹ aiye.
- f Mo f’iyin ailopin
Fun Ọlọrun Ọmọ;
p T’ O f’ ẹjẹ Rẹ̀ wẹ̀ wa,
Kuro ninu egbé;
Nisisiyi O wà l’Ọba,
O nri eso irora Rẹ̀.
- f Mo f’iyin ailopin
Fun Ọlọrun Ẹmí:
Ẹni f’ agbara Rẹ̀,
Sọ ẹlẹṣẹ d’ ayè.
O pari iṣẹ igbala,
ff O si fi ayọ kun ọkàn.
- f Mo f’iyin ailopin
Fun Olodumare,
‘Wọ Ologo mẹta,
Ṣugbọn ọ̀kanṣoṣo;
B’ O ti ju imọ̀ wa lọ nì,
ff A o ma f’ igbagbọ yin Ọ. Amin.