- f Ọlọrun Olodumare,
Baba, Ọmọ, Ẹmí,
Rirì ẹnit’a kò lè mọ̀,
Ẹnit’ a kò lè ri.
- f Ye! Baba Olodumare,
K’ a warìri fun Ọ;
Ni gbogbo orilẹ ede,
Li a o ma sìn Ọ.
- f Ọlọrun Ọmọ, Ọrẹ wa,
p ‘Wọ t’o rà w padda,
Má jọwọ wa, Olugbala!
Gbà wa patapata.
- A ! Ọlọrun Ẹmi Mimọ́,
‘Wọ olore-ọfẹ;
A bẹ Ọ, fun wa ni imọ́,
K’ a m’Ọlọrun n’ ifẹ.
- f Ọkanṣoṣo ṣugbọn mẹta,
Ẹniu Mẹtalọkan,
Ọlọrun awamaridi,
Ẹni Mẹtalọkan !. Amin.