- f Baba, Ẹlẹda wa,
Gbọ orin iyin wa
L’aiye ati l’ọrun,
Baba Olubukun:
cr Iwọ l’ogo ati iyin,
Ọpẹ, ati ọla yẹ fun.
- f ‘Wọ Ọlọrun Ọmọ,
T’ O ku lati gbà wa;
Ẹnit’ O ji dide,
Ti O si goke lọ;
cr Iwọ l’ogo ati iyin,
Ọpẹ, ati ọla yẹ fun.
- f Si Ọ Ẹmi Mimọ́,
Ni a kọrin iyin:
Iwọ t’o f’imọlẹ
Iye si ọkàn wa;
cr Iwọ l’ogo ati iyin,
Ọpẹ, ati ọla yẹ fun.
- p Mimọ́, mimọ́, mimọ́,
N’ iyin Mẹtalọkan;
L’ aiye ati l’ ọrun,
f L’ a o ma kọrin pe,
cr Iwọ l’ogo ati iyin,
Ọpẹ, ati ọla yẹ fun. Amin.