- f Ẹ fi ogo fun Baba,
Nipa Ẹniti a wà;
O ngbọ adura ewe,
O nf’eti si orin wọn.
- f Ẹ fi ogo fun Ọmọ,
Kristi, ‘Wọ ni Ọba wa;
ff Ẹ wá, ẹ kọrin s’okè,
S’ Ọdagutan ẹlẹṣẹ.
- f Ogo fun Ẹmi Mimọ́,
Bi ọjọ Pentikọsti;
Rù aiya awọn ewe,
F’ orin mimọ́ s’ ète wọn
- ff Ogo ni l’oke ọrun,
Fun Ẹni Mẹtalọkan;
Nitori ihin rere,
Ati ìfẹ Ọlọrun. Amin.