- f Baba orun, ‘jinlẹ ‘fẹ Rẹ,
L’o wa Oludande fun wa;
p A wolẹ niwaju ‘tẹ Rẹ,
mf Nawọ ‘dariji Rẹ si wa.
- f Ọmọ Baba, t’O d’Enia,
Woli, Alufa, Oluwa,
p A wolẹ niwaju ‘tẹ Rẹ,
mf Nawọ igbala Rẹ si wa.
- f Ẹmi at’ aiyeraiye lai,
Emi ti njí oku dide,
p A wolẹ niwaju ‘tẹ Rẹ,
mf Nawọ isọji Rẹ si wa.
- f Jehofa, Baba, Ọmọ, Ẹmi
‘Yanu ‘jinlẹ Mẹtalọkan,
p A wolẹ niwaju ‘tẹ Rẹ,
mf Nawọ emi ‘ye Rẹ si wa. Amin.