- f Ọlọrun Mẹtalọkan,
Ọba ilẹ at’ okun;
Gbọ ti wa bi a ti nkọ
Orin iyin Rẹ.
- f ‘Wọ imọlẹ, lowuro,
Tan ‘mọlẹ Rẹ yi wa ka:
Jẹ ki ẹ̀bun rere Rẹ
p M’ aiya wa balẹ̀.
- f ‘Wọ ‘mọlẹ, nigb’ orùn wọ̀,
K’a ri idariji gbà;
Ki alafia ọrun
p F’ itura fun wa.
- f Ọlọrun Mẹtalọkan !
Isin wa laiye kò to !
A nreti lati dapọ
Mọ awọn t’ọrun. Amin.