- f Baba oke Ọrun,
T’ imọlẹ at’ ifẹ,
Ẹni ‘gbani!
‘Mọlẹ t’ a kò le wò,
Ifẹ t’ a kò le sọ,
Iwọ Ọba airi,
Awa yin Ọ.
- Kristi Ọmọ lailai,
‘Wọ t’o di enia,
Olugbala:
Ẹni giga julọ,
Ọlọrun, Imọlẹ,
Aida at’ Ailopin,
mp A kepè Ọ.
- f Iwọ Ẹmi Mimọ,
T’ ina Pẹntikọst’ Rẹ̀,
Ntàn titilai;
Maṣ` aitu wa ninu,
p L’aiye aginju yi:
cr ‘Wọ l’a fẹ, ‘Wọ l’a nyin;
A juba Rẹ.
- f Angẹl’ e lù dùru,
K’orin t’awa ti nyin;
p Jumọ dalu;
ff Ogo fun Ọlọrun,
Mẹtalọkanṣoṣo;
A yìn Ọ tit’ aiye
Ainipẹkun. Amin.