APA I p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Olodumare! mf Ni kutukutu n’iwọ o gbọ orin wa; p Mimọ́, mimọ́, mimọ́! Oniyọnu julọ! f Ologo mẹta lai Olubukun!
mf Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! awọn t’ọrun nyìn, Nwọn nfi ade wura wọn lelẹ̀ y’itẹ ka: cr Kerubim, Serafim nwolẹ̀ niwaju Rẹ. f.di Wọ t’ O ti wà, t’O si wà titi la:
p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! b’ okunkun pa Ọ mọ, Bi oju ẹlẹṣẹ kò lè ri ogo Rẹ. mf Iwọ nikan l’O mọ́, kò tun si ẹlomì, Pipe ‘nu agbara ati n’ ifẹ.
p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Olodumare ! ff Gbogbo iṣẹ rẹ n’ ilẹ̀ l’okè l’ o nyìn Ọ; f.cr Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Oniyọnu julọ, ff Ologo mẹta, lai Olubukun!
APA II
p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Olodumare! Baba, Ọmọ, Ẹmì, Ẹlẹda Oloto; f Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! olododo julọ! Pipe ‘nu ìwa, lai Olubukun.
f Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! gbogbo aiye gberin, Kọrin ‘yìn; k’ aiye yin Ẹni Mẹtalọkan, f Ọlọrun Alagbara, Ọlọrun Olufẹ, Olupamọra, Olore ọfẹ.
f Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Yọ̀, ẹni rapada, Da ohun nyin pọ̀ mọ t’awọn ti nyin l’ ọrun; ff Titi lai ni k’ẹ yin; “Mimọ́, mimọ́, mimọ́!” F’ Ẹni Mẹtalọkan aiyeraiye.
p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Olodumare! Ogo, Ọla, Ọgbọn, Agbara ni Tirẹ; ff Mimọ́ fun Ẹni Mimọ́ ti o gunwá, cr “Ẹlẹru ni iyin, Ẹni yanu”. Amin.