- mf Ẹmi ‘bukun ti a nsìn
Pẹlu Baba at’ Ọrọ,
Ọlọrun aiyeraiye;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- cr Ẹmi Mimọ, ‘Daba ọrun,
Irì ti nsẹ̀ lat’ òke,
Ẹmi ‘yè at’ iná ‘fẹ;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- mf Isun ipá at’ ìmọ,
Ọgbọn at’ ìwa-mimọ,
Oye, imọran, ẹ̀ru;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- mf Isun ifẹ, alafia,
Suru, ibisi ‘gbagbọ,
‘Reti, ayọ̀ ti ki tan;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- cr Ẹmi Afọnahan ni,
Ẹmi ti nmú ‘mọlẹ wá,
Ẹmi agbara gbogbo;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- mp ‘Wọ t’o mu Wundia bi,
Ẹni t’ ọrun t’ aiye mbọ,
T’a ran lati tun wa bi;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- cr ‘Wọ ti Jesu t’ oke ran
Wa tu enia Rẹ̀ ninu,
Ki nwọn má ba nikan wà,
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- Wọ t’O nf’ore kun Ijọ,
T’O nfi ifẹ Baba han,
T’O nmu k’o ma ri Jesu;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- mf Wo ti nf’ onjẹ iye,
At’ otitọ na bọ́ wa,
Ani, On t’O ku fun wa;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- F’ẹ̀bun meje Rẹ fun ni,
Ọgbọn, lati m’Ọlọrun,
Ipá lati kò ọta;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- mf Pa ẹ̀ṣẹ run lọkà wa,
To ifẹ wa si ọ̀na,
B’a ba nṣẹ̀ Ọ, mu surù,
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- cr Gbe wa dide, b’a ṣubu,
Ati nigba idanwo,
Sa pè wa pada pẹ̀l´;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- mf Wá, k’O mu ailera le,
F’igboiya fun alarẹ,
Kọ wa l’ọ̀rọ t’a o sọ;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- mf Wá ràn ọkàn wa lọwọ,
Lati mọ̀ otitọ Rẹ,
Ki ‘fẹ wa le ma gbona;
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- mf Pa wa mọ l’ọna toro
Ba wa wi nigb’a nṣako,
Ba wa bẹbẹ l’ adura,
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa.
- f Ẹni Mimọ, Olufẹ,
Wá gbe inu ọkàn wa;
Ma fi wa silẹ titi:
p Ẹmi Mimọ, gbọ ti wa. Amin.