- mf Si Ọ, Olutunu ọrun,
Fun ore at’ agbara Rẹ,
f A nkọ Alleluya.
- Si Ọ, ifẹ ẹnit’ o wà
Ninu majẹmu Ọlọrun,
A nkọ Alleluya.
- mf Si Ọ, Ohùn Ẹniti npè
Aṣako kuro n’nu ẹṣẹ,
f A nkọ Alleluya.
- Si Ọ, agbara Ẹniti
O nwẹ̀ ni mọ, t’o nwò ni sàn,
A nkọ Alleluya.
- mf Si Ọ, ododo Ẹniti
Gbogbo ‘leri Rẹ̀ jẹ tiwa,
f A nkọ Alleluya.
- Si Ọ, Olukọ at’ Ọrẹ,
Amọna wa totọ d’ opin,
A nkọ Alleluya.
- mf Si Ọ, Eniti Kristi ran,
f Ade on gbòngbo ẹ̀bun Rẹ̀.
ff A nkọ Alleluya.
- f Si Ọ, Enit’ o jẹ ọkan
Pẹlu Baba ati Ọmọ,
ff A nkọ Alleluya. Amin.