f Baba wa ọrun, awa de, p Awa alailagbara; cr Fi Ẹmi Mimọ́ Rẹ kún wa, K’o sọ gbogbo wa d’ọtun. f Wá! Ẹmi Mimọ́, jare wá! F’ède titun s’ọkàn wa. Ẹbun nla Rẹ nì l’a ntọrọ, T’ ọjọ nla Pentikọsti.
f Ranti ileri Rẹ, Jesu, Tu Ẹmi Rẹ s’ara wa: Fi alafia Rẹ fun wa, T’ aiye kò lè fifun ni. f Wá! Emi Mimọ́, jare wá! p Pa ẹ̀ṣẹ run l’ọkàn wa. Ẹbun nla Rẹ nì l’a ntọrọ, T’ ọjọ nla Pentikọsti.
Adaba ọrun! Bà le wa, f Fi agbara Rẹ fun wa; Ki gbogbo orilẹ edè Tẹriba f’Olugbala. K’ a gburo Rẹ jakejado Ilẹ̀ okunkun wa yi. p Ẹbun nla Rẹ nì l’ a ntọrọ, T’ ọjọ nal Pentikọsti. Amin.