- mf Ẹmi Mimọ́ ‘Daba ọrun,
Wá mu itunu sọkalẹ;
f Ṣe Ogá at’ Olutọ wa,
Ma pẹlu gbogbo èro wa.
- mf Jọ fi otitọ Rẹ hàn wa,
K’ a lè fẹ k’a so m’ọna Rẹ;
p Gbin ife totọ s’ọkàn wa,
K’a má lè pada lẹhin Rẹ.
- cr Mu wa k’a tọ̀ ọ̀na mimọ́,
T’a lé gbà d’ọdọ Ọlọrun;
Mu wa tọ̀ Krist, Ọna, Iye,
Má jẹ ki awa ṣinà lọ.
- f Mu wa t’Ọlọrun, ‘simi wa,
K’ a lè ma ba gbe titi lai:
Tọ́ wa s’ọrun, k’a lè n’ipin,
L’ọwọ Ọtun Ọlọrun wa. Amin.