Hymn 274: Descend, gracious Holy Ghost

Emi Mimo sokale

  1. mf Ẹmi Mimọ́ sọ̀kalẹ̀,
    Ba wa gbe ni aiye yi;
    Fi ohun ọrun hàn ni,
    cr Si ba ni sìn Ọlọrun.

  2. Ẹṣẹ wà ni ọkàn wa,
    Ti a kò lè fi silẹ;
    f Agbara wa kò to ṣe,
    Bi ‘Wọ kò ba pẹlu wa.

  3. f Awa nfẹ k’ẹ̀ṣẹ parun,
    L’ ọkàn ati l’ara wa;
    p Wá, Ẹmi Mimọ́, jọ wá,
    K’o wẹ gbogbo ẹ̀ṣẹ nu.

  4. f Ọlọrun, ‘Wọ l’awa nfẹ,
    cr Fi Ẹmi Rẹ na fun wa;
    K’a lè pa ofin Rẹ mọ,
    K’a si rìn ni ọ̀na Rẹ. Amin.