- mf Wá mi is wa, Ẹmi Mimọ́,
Tàn ‘ná ọrun si ọkàn wa;
Ẹmi a f’ororo yànn,
Ti ‘f’ẹbun meje Rẹ̀ funni,
- cr Iṣẹ nla Rẹ atoke wa
N’itunu, ìye, ina ifẹ:
F’imọlẹ Rẹ igbagbogbo,
Le okùnkùn ọkàn wa lọ.
- mf F’ororo ore-ofẹ Rẹ
Pa oju eri wa k’o dán;
di L’ọta jinà s’ibugbe wa:
p Ire n’igbé ‘biti ‘Wọ nṣọ́.
- mf Kọ wa k’a mọ̀ Baba, Ọmọ,
Pẹlu Rẹ l’ọkanṣoṣo;
cr Titi aiye ainipẹkun,
Ni k’eyi ma jẹ orin wa:
f Lai, iyìn, ẹyẹ, ni fun Ọ,
Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ. Amin.