Hymn 272: Come, Thou Holy Paraclete

Wa, Parakliti mimo

  1. mp Wa, Parakliti mimọ,
    Lat’ ibugbe Rẹ ọrun,
    cr Rán itanṣan ‘mọlẹ wa.

  2. mf Baba talaka, wá ‘hin,
    Olufunni l’ẹbun, wá
    Imọlẹ ọkàn, jọ wá.

  3. p Wọ n’isimi n’nu lala,
    Iboji ninu oru,
    Itunu ninu ‘pọnju.

  4. mf Wọ ‘mọlẹ t’o mọ gara,
    cr Tàn sinu aiya awọn
    Enia Rẹ olòtọ.

  5. Laisi Rẹ, kil’ ẹda jẹ?
    Iṣẹ at’ èro mimọ,
    Lat’ ọdọ Rẹ wa ni nwọn.

  6. p Eleri, sọ di mimọ,
    Agbọgbẹ, má ṣai wo sàn,
    Alaileso, mu s’eso.

  7. Mu ọkàn tutù gbona,
    M’ alagidi tẹriba
    Fa aṣako wá jẹjẹ.

  8. cr F’Ẹmi ‘jinlẹ Rẹ meje,
    Kún awọn olotọ Rẹ,
    F’agbara Rẹ ṣ’abo wọn.

  9. f Rán or’ọfẹ Rẹ sihin,
    Ẹkún igbala l’aiye,
    At’ alafia l’ọrun. Amin.