- f Ọjọ isimi Ọlọrun,
Ọjọ ti o dara julọ;
Ti Ọlọrun ti fi fun wa,
K’ awa k’o simi ninu rẹ.
- Ijọ mẹfa l’ O fi fun wa,
K’ a fi ṣe iṣẹ wa gbogbo;
Ṣugbọn ọjọ keje yatọ̀,
Ọjọ ‘simi Ọlọrun ni.
- mf K’ a fi ‘ṣẹ asan wa silẹ̀,
Ti awa nṣe n’ ijọ mẹfa;
Mimọ̀ ni iṣẹ ti oni,
Ti Ọlọrun Oluwa wa.
- f A pàra de nisisiyi
Ninu ile Ọlorun wa;
Jẹk’a kọrin didùn si I,
Li owurọ ọjọ oni.
- Ni kutukutu ‘jọ keje
Ni ọjọ isimi mimọ́
ff Jẹ k’ a jumọ kọrin didùn,
Jẹ k’ a si jumọ gbadura. Amin.