Hymn 269: Thou Holy Spirit, come down

Emi Mimo sokale

  1. mf Ẹmi Mimọ́ sọkale,
    Fi ohun ọrun han;
    K’ o mu imọlẹ w’aiye,
    Si ara enia,
    K’ awa t’a wà l’ okunkún,
    Ki o le ma riran,
    p ‘Tori Jesu Kristi kú
    Fun gbogbo enia.

  2. K’o fi hàn pe ẹlẹṣẹ
    Ni emi nṣe papa;
    K’emi k’o le gbẹkẹ mi
    Le Olugbala mi,
    Nigbati a wẹ̀ mi nù
    Kuro ninu ẹṣẹ,
    Emi o lè fi ogo
    Fun Ẹni-mimọ́ na.

  3. f K’ o mu mi ṣe afẹri
    Lati tọ Jesu lọ;
    K’o jọba ni ọkàn mi,
    K’o sọ mi di mimọ̀;
    Ki ara ati ọkàn,
    K’o dapọ lati sìn
    Ọlọrun Ẹni-Mimọ́,
    Mẹtalọkanṣoṣo. Amin.