- mf Ẹmi Mimọ́, ‘dàba ọrun,
cr Wá li agbara Rẹ;
K’o da iná ifẹ mimọ́
Ni ọkàn tutù wa.
- cr Wò b’a ti nrapala nihin,
T’a fẹ ohun asan;
Ọkàn wa kò lè fò k’ o lọ,
K’ o de ‘b’ ayọ̀ titi.
- Oluwa, ao ha wà titi
p Ni kikú oṣi yi?
Ifẹ wa tutù bẹ si Ọ,
Tirẹ tobi si wa.
- f Ẹmi Mimọ́ ‘dabà orun,
cr Wá ni agbara Rẹ;
Wá daná ‘fẹ Olugbala,
Tiwa o si gbina. Amin.