mf Ẹmi Ẹlẹda, nipa Rẹ L’a f’ipilẹ aiye sọlẹ, p Maṣai bẹ̀ gbogbo ọkàn wò, Fi ayọ Rẹ si ọkàn wa; Yọ wa nin’ ẹṣẹ at’ egbe, K’ o fi wa ṣe ibugbe Rẹ.
f Orisun imọlẹ ni Ọ, Ti Baba ti ọe ileri; Iwọ Ina mimọ ọrun, Fi ‘fẹ ọrun kun ọkàn wa; p Jọ tu ororo mimọ Rẹ Sori wa bi a ti nkọrin.
mp Da ọ̀pọ ore-ọfẹ Rẹ, Lat’ ọrun sori gbogbo wa; cr Jẹ k’a gba otitẹ Rẹ gbọ, K’a si ma ṣa rò l’ọkàn wa; F’ ara Rẹ hàn wa k’ a le ri Baba at’Ọmọ ninu Rẹ.
f K’a fi ọla ati iyìn Fun Baba Olodumare; K’a yìn okọ Jesu logo, Ẹnit’ o kú lati gbà wa; Iyin bakanna ni fun Ọ, Parakliti Aiyeraiye. Amin.