Hymn 266: Lord God the Holy Ghost

Emi Olorun mi

  1. mf Ẹmi Ọlọrun mi,
    L’ọjọ ‘tẹwọgbà yi;
    Gege b’ọjọ Pentikọsti,
    f Sọkalẹ l’agbara.
    Lọkàn kan l’a pade
    Ninu ile Rẹ yi;
    A duro de ileri Rẹ.
    p A duro de Ẹmi.

  2. f B’ iro ìji lile
    Wá kun ‘nu ile yi;
    cr Mí Ẹmi iṣọkan si wa,
    Ọkàn kan, imọ̀ kan.
    Fun ewe at’ agba
    L’ọgbọ́n at’òke wá;
    Fi ọkàn gbigbona fun wa:
    K’a yìn, k’a gbadurà.

  3. mp Ẹmi imọlẹ, wá
    Le òkunkun jade;
    Siwaju ni k’ imọlẹ tàn
    Titi d’ọsangangan,
    Ẹmi otitọ wá,
    Ṣ’ amọna wa titi;
    Ẹmi Isọdọmọ, si wa
    S’ọkàn wa i mimọ. Amin.