- f Gbani t’ Ọlọrun sọkalẹ,
O wá ni ibinu;
Ará sì nsan niwaju Rẹ̀,
Okunkun on ina.
- p Nigbat’ o wá nigba keji,
O wá ninu ifẹ;
pp Ẹmi Rẹ̀ sì ntù ni lara,
B’ afẹfẹ owurọ̀.
- f Iná Sinài ijọ kini,
T’ọwọ rẹ̀ mbù soke,
mp Sọkalẹ jẹjẹ bi ade,
Si ori gbogbo wọn.
- f Bi ohùn ẹ̀ru na ti dún,
L’eti Israeli,
Ti nwọn si gbọ iró ipè,
To m’ohùn angẹl gbọ̀n.
- mf Bẹ gẹgẹ nigbat’ Ẹmi wá
Bà le awọn Tirẹ̀,
cr Iró kan si ti ọrun wa,
Iró iji lile.
- f O nkun Ijọ Jesu, o nkun
Aiye ẹsẹ yika;
mp L’ọkàn alaigbọràn nikan
Ni àye kò si fun.
- mf Wa, Ọgbọn, Ifẹ, at’ Ipa,
Mu ki eti wa ṣí;
p K’a má sọ akoko wa nù;
Ki ‘fẹ Rẹ le gbà wa. Amin.