- mp Olurapada wa, k’On to
Dagbere ikẹhìn,
O fi Olutunu fun ni,
Ti mba wa gbe.
- p O wá ni àws àdaba
O nà ìyẹ bò wa;
O tàn ‘fẹ on Alafia
Sori aiye.
- mf O de, o mu ‘wà-rere wá,
Alejo Olore;
Gbat’ o ba r’ ọkàn ìrẹlẹ
Lati ma gbe.
- p Tirẹ̀ l’ ohùn jẹjẹ t’a ngbọ,
Ohùn kẹ́lẹkẹlẹ;
Ti nbaniwi, ti nl’ ẹ́ru lọ,
Ti nsọ t’ ọrun.
- Gbogbo iwa-rere t’a nhù,
Gbogbo iṣẹgun wa;
Gbogbo èro iwa-mimọ,
Tirẹ̀ ni nwọn.
- mf Ẹmi Mimọ, Olutunu,
F’ ìyọ́ bẹ̀ wa wò;
cr Jọ, ṣ’ ọkán wa n’ ibugbe Rẹ,
K’o yẹ fun Ọ. Amin.