p Kúkuru l’ọj’ aiye wa, Diẹ l’ọjọ arò; cr Aiye ti kò l’opin mbẹ, Nibit’ ẹkùn kò si.
mf A ! ère wo l’o to yi: Isimi ailopin; At’ile nla t’ó dara, F’ẹlẹṣẹ bi awa.
cr L’aiye yi awa njagun, L’ọrun a o d’ade, Ade ti ki dibajẹ, Ti y’o ma dán titi.
mf Nibẹ l’awa o gbe ri Ẹnit’ a gbẹkẹle; Iye awọn to ba mọ, Ni yio jẹ tirẹ̀.
cr Owurọ ọjọ na mbọ, Okunkun y’o ká lọ, f Awọn ọlọkàn pipe Y’o mà ràn bi òrun.
ff Ọlọrun at’ipin wa, N’nu ẹ̀kún ore Rẹ, N’ibẹ ni a o ma wo A o yin lojukoju.
APA II
mp A! ilu daradara, Mo fẹ lati ri ọ, di Ọpọlọpọ ni nsunkun Fun ‘fẹ lati ri Ọ, cr Ogo ti mbẹ ninu rẹ, Ororo ni f’ọkàn, Egbogi ni fun aisan, Ifẹ ni, ìye ni.
mf Ibugbe kanṣoṣo na, Paradise ayọ, Nibit’ omije ki dé, Ẹrìn ni ‘gbagbogbo; f Ọdagutan ti a pa, On ni ẹwà ibẹ̀; Awọn ti a rapada, Nkọrin ibukun Rẹ̀.
cr Okuta jasper didan, L’a fi mọ odi rẹ; Oniruru okuta L’a fi tẹ́ ita rẹ; Ilu na dara pupọ, O mọ bi kristali; ff Awọn mimọ ni ngbe ‘be, Kristi n’ Ipilẹ rẹ̀.
mf Okun ti kò n’ebute, Ọjọ ti ko n’opin; p Orisun ‘tura didun, Fun awọn alarẹ, cr L’or’ Apat’ aiyeraiye L’a mọ odi rẹ si; Tirẹ l’ade aṣẹgun, Tirẹ l’ade wura. Amin.