- mf Oru kò si l’ọrun,
N’ilu mimọ l’oke;
Iṣẹ ko le mu arẹ̀ wà,
Iṣẹ pa jẹ ifẹ.
- Arò kò si l’ọrun,
Ayọ̀ titilai ni;
p Ẹkun wà l’ohun iṣaju,
Ti o ti rekọja.
- mf Ẹṣẹ k` si l’ọrun,
cr Wo ajọ ‘bukun na;
f Mimọ ni aṣọ àla wọn,
Mimọ ni orin wọn.
- p Iku kò si l’ọrun,
Gbogb’ awọn t’o de ‘bẹ̀,
cr Ti gbà ere aiku titi,
Nwọn kò tun le ku mọ.
- mf Jesu, ṣ’amọna wa,
cr Tit’ oru, at’ arò,
f T’ ẹṣẹ, at’ iku yio tan;
T’ a o si de ọrun. Amin.