Hymn 261: We speak of the realms of the Blest

A nsoro ile ’bukun ni

  1. mf A nsọ̀rọ ilẹ ‘bukun nì,
    Ilẹ didan, at’ ilẹ ẹwà;
    ‘Gbagbogbo l’a nsọ t’ogo rẹ̀;
    p Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!

  2. mf A nsọ̀rọ ita wura rẹ̀,
    Ọṣọ odi rẹ̀ ti kò l’ẹgbẹ;
    ‘Fajì rẹ̀ kò ṣe f’ẹnu sọ;
    p Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!

  3. mf A nsọ p’ ẹṣẹṣ kò si nibẹ,
    Kò s’aniyan at’ ibanujẹ,
    Pẹlu ‘danwo lode, ninu;
    p Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!

  4. mf A nsọrọ orin iyìn rẹ̀,
    Ti a kò le f’orin aiye wé;
    B’o ti wù k’orin wa dùn to;
    p Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!

  5. mf A nsọrọ isin ifẹ rẹ̀,
    Ti agbada t’ awọn mimọ nwọ̀,
    Ijọ akọbi ti oke;
    p Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ!

  6. mf Jọ, Oluwa, t’ibi t’ire,
    Sa ṣe ẹmi wa yẹ fun ọrun;
    Laipẹ, awa na yio mọ̀,
    p Y’o ti dùn tó lati de ‘bẹ̀. Amin.