f Paradise ! Paradise ! Tani kọ fẹ ṣimi ? Tani kọ fẹ ‘lẹ ayọ na, Ilẹ alabùkun ; Nib’ awọn olotọ Wà lai ninu ‘mọle, ff Nwọn nyọ̀ nigbagbogbo, Niwaju Ọlọrun.
f Paradise ! Paradise ! p Aiye ndarugbo lọ ; Tani kò si fẹ lọ simi, Nib’ ifẹ ki tutu ? Nib’ awọn olotọ, &c.
f Paradise ! paradise ! p Aiye yi ma su mi ! Ọkàn mi nfà sọdọ jesu, Emi nfẹ r’ oju pẹ̀ ; Nib’ awọn olotọ, &c.
f Paradise ! Paradise ! Mo fẹ ki nye dẹṣẹ, Mo fẹ ki nwà lọdọ Jesu, Li ebute mimọ; Nib’ awọn olotọ, &c.
f Paradise ! Paradise ! Nkò ni duro pẹ mọ; Nisìyí b’ẹnipe mo ngbọ Ohùn orin ọrun; Nib’ awọn olotọ, &c.
Jesu, Ọba Paradise, Pa mi mọ n’nu ‘fẹ Rẹ; Mu mi de ilẹ ayọ̀ na, Nib’ isimi l’oke; Nib’ awọn olotọ Wà lai ninu ‘mọle, ff Nwọn nyọ̀ nigbagbogbo, Niwaju Ọlọrun. Amin.