Hymn 26: Great Shepherd of Thy people, hear;

Olusagutan eni re

  1. f Oluṣaguntan ẹni rẹ
    Fi oju Rẹ han wa,
    ‘Wọ fun wa n’ile adura
    M’ ọkan wa gbadura.

  2. mf K’ ifẹ ati alafia
    K’ o ma gbe ile yi;
    F’ irọra f’ ọkàn ipọnju
    mf M’ ọkan ailera le.

  3. K’ a fi ‘gbagbọ gbọ́ ọ̀rọ Rẹ,
    K’ a fi ‘gbagbọ bẹ̀bẹ;
    Ati niwaju Oluwa
    K’ a ṣe aroye wa. Amin.