Hymn 259: For ever with the Lord!

Lai lodo Oluwa

  1. mf “Lai lọdọ Oluwa!”
    Amin, bẹni k’o ri.
    cr Iye wà ninu ọrọ na,
    Aiku ni titi lai.
    mp Nihin ninu ara,
    Mo ṣako jina si;
    cr Sibẹ, alalẹ ni mo nfi,
    Ọjọ kan sunmọle!

  2. mf Ile Baba loke,
    Ile ọkàn mi ni;
    Emi nfi oju igbagbọ
    Wò bode wura rẹ̀!
    p Ọkàn mi nfà pipọ,
    S’ ile na ti mo fẹ,
    cr Ilẹ didan t’ awọn mimọ,
    Jerusalem t’ Ọrun.

  3. di Awọsanma dide,
    Gbogbo èro mi pin;
    Bi adaba Noa, mo nfò
    Lari ìji lile,
    cr Ṣugbọn sanma kurò,
    Iji sì rekọja,
    Ayọ̀ ati Alafia
    Sì gbà ọkàn mi kan.

  4. mf Lorọ ati l’ alẹ,
    Lọsan ati loru,
    Mo ngbọ orin ọrun, bori
    Rudurudu aiye,
    ff Ọrọ ajinde nì,
    Hiho iṣẹgun nì,
    Lẹkan si, “Lai lọd’ Oluwa”
    Amin, bẹni k’o ri. Amin.