- mf Lẹhìn aiye òkunkun yi,
Ogo ailopin mbẹ;
At’ilu ayọ̀ ti ki tan,
T’ oju ẹda ko ri.
- Ilu ẹwa! oju wa ‘ba
Ri ‘daji ayọ́ rẹ,
Ọkan wa iba ti fẹ to
Lati f’ aiye silẹ!
- p Aìsan on ‘rora ki de ‘bẹ̀,
cr Ibanujẹ kò si;
f Ilera ni lọjọ gbogbo,
Adùn ti kò lopin.
- mf Oru kó si n’ ilu wọnnì,
Ọsan ni titi lai;
Ẹṣẹ, orison ègbé wa,
Kò le wọ̀ ‘bẹ̀ titi.
- f A! k’ ireti ọrun wa yi
Mu ọkàn wa gbóna,
K’ igbagbọ at’ ifẹ nla yi
M’ èro wa lọ soke.
- Oluwa, ‘lanu ṣe wa yẹ
Fun àgbalá ọrun;
f Si sọ f’ọkàn wa k’o dide
Dapọ m’ awọn t’ ọrun. Amin.