Hymn 257: A mount exist so high and bright!

Oke kan mbe t’ o ga

  1. f Oke kan mbẹ t’ o ndan t’ o ga,
    Nibi t’ a m’ Ọlọrun;
    O wà l’ okerè ni ọrun,
    Itẹ Ọlọrun ni.

  2. mf Tal’ awọn t’o sunmọ ibẹ̀,
    Lati wò itẹ Rẹ̀?
    Ẹgbarun wọn t’ o wà nibẹ̀,
    Ọmọde bi awa.

  3. Olugbala w’ ẹ̀ṣẹ wọn nù,
    O sọ wọn di mimọ́;
    Nwọn f’ ọ̀rọ Rẹ̀, nwọn f’ ọjọ Rẹ̀,
    Nwọn fẹ, nwọn si ri i.

  4. mf Labẹ ọpọ oko tutú,
    p L’ara wọn simi si:
    Nwọn ri ‘gbala ọkàn wọn he,
    Laiya Olugbala.

  5. f K’ awa k’ o rìn bi nwọn ti rìn,
    Ipa t’ o lọ s’ọrun;
    Wá idariji Ọlọrun,
    T’ o ti dariji wọn.

  6. p Jesu ngbọ́ irẹlẹ ẹkun,
    T’ o mu ọkàn d‘ ọtun;
    Lori òke t’ o ndán, t’ o ga,
    f L’ awa o ma wo Ọ. Amin.