mf Ilẹ ayọ̀ kan wà Ti o jinà, Ni b’ awọn mimọ́ wà; Nwọn nràn b’ orun; cr A! nwọn nkọrin didùn, Yiyẹ, l’Olugbala wa: Ki ìyin Rẹ̀ k’ o ró, f Yìn yìn lailai.
mf Wà silẹ ayọ̀ yi, Wá, wá k’ a lọ; Ẹ ṣe nṣiyemeji? Ẹ ṣe nduro? cr Ao wà l’alafia, Kuro l’ ẹ̀ṣẹ at’ arò: A o ba ọ jọba, L’ayọ̀ lailai.
f Oju gbogbo wọn ndàn, N’ ilẹ ayò; p N’ ipamọ Baba wa, Ifẹ ki ‘kú; cr Njẹ sure lọ s’ogo, ff Gba ade at’ ijọba; T’ o mọ́ ju orún lọ, Jọba titi. Amin.