- mf Jerusalem t’ọrun,
Orin mi, ilu mi!
Ile mi bi mba kú,
Ẹkún ibukun mi;
cr Ibi ayọ̀!
Nigbawo ni,
Ngo r’oju rẹ,
Ọlọrun mi?
- mf Odi rẹ, ilu mi,
L’ a fi pearl ṣe l’ ọ̀ṣọ́;
f ‘Lẹ̀kun rẹ ndan fun yìn,
Wura ni ita rẹ!
cr Ibi ayọ̀ &c.
- mp Orùn ki ràn nibẹ,
Bẹni kò s’ oṣupa;
A kò wa iwọnyi,
Krist n’ imọlẹ ibẹ.
cr Ibi ayọ̀ &c.
- mf Nibẹ l’ Ọba mi wà,
p T’ a dá l’ ẹbi l’ aiye;
f Angẹli nkọrin fun,
Nwọn si ntẹriba fun.
cr Ibi ayọ̀ &c.
- Patriark’ igbani,
Par’ ayọ wọn nibẹ;
Awọn woli, nwọn nwò
Ọmọ alade wọn.
cr Ibi ayọ̀ &c.
- mf Nibẹ ni mo lè ri
Awọn Apostili;
At’ awọon akorin,
Ti nlù harpu wura,
cr Ibi ayọ̀ &c.
- mp Ni agbala wọnni,
Ni awọn Martir wà;
cr Nwọn wọ̀ aṣọ àla,
Ogo bo ọgbẹ wọn.
Ibi ayọ̀ &c.
- p T’ emi yi sa su mi,
Ti mo gb’ agọ Kedar
Ko si ‘ru yi loke:
cr Nibẹ ni mo fẹ lọ.
f Ibi ayọ̀ &c. Amin.