Hymn 254: At the end of this wicked life;

Lehin aiye buburu yi

  1. mp Lẹhin aiye buburu yi,
    p Aiye ẹkun on òṣi yi,
    Ibi rere kan wà;
    Ayipada kò si nibẹ̀,
    Kò s’oru, a f’ọ̀sán titi,
    p Wi mi, ‘wọ o wà nibẹ?

  2. mf ‘Lẹ̀kun ogo rẹ̀ tì m’ ẹ̀ṣẹ,
    Ohun eri kò lè wọ ‘bẹ̀,
    Lati b’ ẹwà rẹ̀ jẹ;
    f L’ ebute daradara ni,
    A kò ni gburo egún mọ,
    p Wi mi, ‘wọ o wà nibẹ?

  3. Tan’ y’o de ‘bẹ? Onirẹlẹ,
    T’o f’ ibẹru sin Oluwa,
    T’ nwọn kò náni aiye:
    Awọn t’ a f’ Emi mimọ́ tọ́,
    Awọn t’ o nrin lọnà tóro.
    Awọn ni o wà nibẹ̀. Amin.