- mf Jerusalẹm ibi ayọ̀,
T’ o ṣe ọwọn fun mi;
cr Gbawo n’ iṣẹ mi o pari,
L’ayọ̀ l’ alafia?
- mf ‘Gbawo ni oju mi y’o ri,
Ẹnu-bode pearl Rẹ?
Odi Rẹ to le fun gbala,
Ita wura didan.
- ‘Gbawo, ilu Ọlọrun mi,
L’ emi o d’ afin Rẹ?
cr Nibiti ijọ ki ‘tuka,
Nib’ ayọ̀ ailopin.
- mf Eṣe t’ emi o kọ̀ iyà,
Ikù at’ ipọnju?
f Mo nwo ilẹ rere Kenaan,
Ilẹ ‘mọlẹ titi.
- Apostili, martir, woli,
Nwọn y’ Olugbala ka;
Awa tikara wa, fẹrẹ̀
Dapọ mọ ogun na.
- mf Jerusalẹm ilu ayọ̀,
Ọkàn mi nfà si ọ:
cr Gbati mo ba ri ayọ̀ rẹ,
Iṣẹ mi y’o pari. Amin.