- f Olor’ Alufa giga kan,
To gb’ẹda wa wọ̀ farahan,
Nibit tempil’ ọrun wà,
Ile Ọlọrun t’a kò kọ́.
- p On, bi Onigbọwọ enia,
To t’ẹjẹ ‘yebiye s’ile,
To npari ‘ṣẹ nla Rẹ̀ l’ọrun,
Olugbala, Ọrẹ enia.
- mf B’o tilẹ goke lọ s’ọrun,
O nfoju ifẹ wò aiye,
Ẹnit’o njẹ́ okọ enia,
O mọ̀ ailera ẹda wa.
- mp Alabajiya wa si mọ̀
Bi ‘rora wa si ti pọ to;
di L’ọrun, o si nranti sibẹ,
pp Omije on ‘waiya jà Rẹ̀.
- mp Ninu ibanujẹ ọkàn,
Ẹni ‘Banujẹ pin n’nu Rẹ̀;
cr O mba wa daro ẹ̀dun wa,
O si nràn òjiya lọwọ.
- f K’ a k’ẹdùn wa lọ sọdọ Rẹ̀,
Pẹlu ‘gboiya, nibi itẹ;
K’a tọrọ agbara ọrun,
Lati yọ wa nigba ibi. Amin.