- mf Jẹ ki m’ni ‘po mi lọdọ Rẹ,
Jesu, iwọ isimi mi;
‘Gbana l’ọkàn mi y’o simi,
ff Y’o si ri ẹ̀kún bukun gbà.
- mf Jẹ ki m’n’ ipò mi lọdọ Rẹ,
K’ emi k’ o lè ri ogo Rẹ:
‘Gbana ni ọkàn ẹ̀tàn mi
Yio ri ẹni f’ ara le.
- mf Jẹ ki m’n’ ipò mi lọdọ Rẹ,
Nibi awọn mimọ́ nyin Ọ:
‘Gbana ni ọkàn ẹ̀ṣẹ mi,
Y’o dẹkun ẹ̀ṣẹ ni dida.
- mf Jẹ ki m’n’ ipò mi lọdọ Rẹ.
Nibi a ki yipò padà;
Nib’ a kò npè, O digboṣe,
ff Titi aiye, titi aiye. Amin.