mf Ile ‘bukun kan wà Lẹhin aiye wa yi, Wahala, irora, At’ẹkún ki dé bẹ̀; cr Igbagbọ y’o dopin, Ao de ‘reti l’ade, f Imọlẹ ailopin Ni gbogbo ibẹ̀ jẹ.
mp Ilẹ kan si tun mbẹ, Ilẹ alafia, cr Awọn Angẹl rere Nkọrin n’nu rẹ̀ lailai; ff Y’itẹ ogo Rẹ̀ ka L’awọn ẹgbẹ mimọ Nwolẹ, nwọn ntẹriba F’ Ẹni Mẹtalọkan.
mf Ayọ wọn ti pọ̀ to! p Awọn to ri Jesu cr Nibit’ o gbe gúnwà T’a si nfi ogo fun; f Nwọn nkọrin iyìn Rẹ̀ Ati t’ iṣẹgun Rẹ̀, Nwọn kò dẹkun rohin Ohun nla t’o ti ṣe.
mf W’ oke, ẹnyin mimọ, Ẹ lé ibẹru lọ p Ọna hihá kanna L’Olugbala ti gbà: cr Ẹ fi suru duro Fun igba die ṣa, f T’ẹ̀rín-t’ẹ̀rín l’On o Fi gbà nyin sọọ Rẹ̀. Amin.