f Ọjọ ‘simi at’ ayọ̀, Ọjọ inu didun, mf Ogùn fun ibanujẹ Ọjọ dida julọ; Ti awọn ẹni giga Niwaju itẹ Rẹ p Nkọ mimọ́, mimọ́, mimọ́, S’ ẹni Mẹtalọkan.
f L’ ọjọ yi ni ‘mọlẹ là, Nigba didà aiye: Ati fun igbala wa Kristi jinde loni: mf L’ ọjọ oni l’ Oluwa Ran Ẹmi t’ ọrun wà; Ọjọ ologo julọ T’ o ni ‘mọlẹ pipe.
mf Orisun ‘tura ni Ọ, L’ aiye aginju yi: L’ ori Rẹ, bi ni Pisga L’ a nwo ‘lè ileri. Ọjọ ironu didùn Ọjo ifẹ mimọ́, Ọjọ ajinde, lati Aiye, si nkan ọrun.
mp L’ oni s’ ilu t’ arẹ̀ mu Ni Manna t’ ọrun bò; f Si ipejọpọ mimọ N’ ipè fadaka ndùn. Nibiti Ihin-rere Ntàn imọlẹ̀ mimọ́, p Omi ìye nṣan jẹjẹ Ti ntù ọkàn lara.
K’ a r’ ore-ọfẹ titun L’ ọjọ ‘simi wa yi, K’ a si dé ‘simi t’ o kù F’ awọn alabukun. f Nibẹ k’ a gbohun soke Si Baba at’ Ọmọ Ati si Ẹmi Mimọ, N’ iyin Mẹtalọkan. Amin