- f Ile ẹwà wọnni, b’o ti dara to!
Ibùgbe Ọlọrun, t’ oju kò ti ri;
Ta l’o fẹ de ibẹ̀, lẹhin aiye yi?
Ta l’o fẹ k’ a wọ̀ on ni aṣọ funfun?
- p Awọn wọnnì ni, t’ o ji nin’orun wọn;
Awọn t’o ni ‘gbagbọ si nkan t’a kò ri;
Awọn t’o k’ aniyàn wọn l’Olugbala,
Awọn ti kò tiju agbelebu Krist.
- cr Awọn ti kò ńani gbogbo nkan aiye,
Awọn t’o lè ṣotọ e oju ikù,
Awọn t’o nrubọ ifẹ̀ l’ojojumọ,
Awọn t’a f’igbala Jesu rà padà.
- f Itiju ni fun nyin, Ọm’ ogun Jesu,
Ẹnyin ara ìlu ibugbe ọrun,
Kinla! ẹ nfi fère at’ ìlu ṣire,
‘Gbat’ o ni k’ẹ ṣiṣẹ, t’o si pe, “Ẹ jà !”
- cr B’ ìgbi omi aiye si ti nkọlù wa,
Jesu Ọba ogo, sọ si wa l’eti,
Adùn t’o wà l’ọrun, ilu mimọ́ nì,
f Nibi t’isimi wà lai ati lailai. Amin.