Hymn 248: He is gone—a cloud of light

O ti lo. Awosanma

  1. p O ti lọ. Awọsanma,
    Ti gba kuro loju wa,
    f Soke ọrun nibiti
    Oju wa kò le tẹle;
    O ti kuro l’aiye yi,
    O ti de ibi mimẹ,
    Lala at’ irora tan,
    Ijà tan, o ti ṣẹgun.

  2. p O ti lọ. Awa sì wá
    L’aiye ẹṣẹ at’ iku;
    A ni ‘ṣẹ́ lati ṣe fun,
    L’aiye t’o ti fisilẹ,
    cr K’a si tẹle ọna Rẹ̀;
    K’a tẹle tọkàntọkan
    K’a s’ọta Rẹ di ọrẹ,
    K’a fi Krist hàn n’iwa wa.

  3. p O ti lọ. On ti wipe,
    “O dara ki Emi lọ,”
    Ni ara ṣa l’o yà wa,
    Ṣugbọn or’ọfẹ Rẹ̀ wa:
    mf On ni awa kò ri mọ,
    A ni Olutunu rẹ̀,
    f Ẹmi Rẹ̀ si jẹ tiwa.
    O ns’ agbara wa d’ọtun.

  4. p O ti lọ. L’ọna kanna,
    L’o yẹ k’ Ijọ Rẹ̀ ma lọ;
    f K’a gbagbe ohun ẹ̀hin,
    K’a si ma tẹ̀ siwaju:
    Ọrọ Rẹ̀ ni ‘mọlẹ wa,
    Titi de opin aiye,
    Nibiti otọ Rẹ̀ wà,
    Y’o pese fun alaini.

  5. p O ti lọ. Lẹkan si i
    A o tun f’ oju wa ri;
    f O wà bakanna l’ọrun,
    Gẹgẹ b’o ti wà l’aiye:
    N’nu ‘bugbe t’o wà nibẹ,
    Y’o pese àye fun wa,
    p Ninu aiye ti mbọ̀ wa,
    A o j’ọkan pẹlu Rẹ̀.

  6. p O ti lọ. Fun ire wa,
    Ẹ jẹ ki a duro dè;
    f O jinde, ko si nihin.
    O ti goke re ọrun;
    Jẹ k’a gb’ ọkan wa soke,
    Sibiti Jesu ti lọ,
    ff Si ọdọ Ọlọrun wa,
    Nibẹ l’alafia wà. Amin.