ff Iwọ ti goke lọ S’ile ayọ ọrun, Lojojumọ yitẹ Rẹ ka L’a ngbọ orin iyìn; p Ṣugbọn awa nduro, Labẹ ẹrù ẹṣẹ; cr Jọ ràn Olutunu Rẹ wa, K’o si mu wa lọ ‘le.
f Iwọ ti goke lọ: p Ṣugbọn ṣaju eyi, O kọja ‘rora kikoro, cr K’o to le de ade; mp Larin ibanujẹ, L’ao ma tẹ̀ siwaju; cr K’ọna wa t’o kun f’omije, Tọ́ wa si ọdọ Rẹ.
f Iwọ ti goke lọ; Iwọ o tun pada; Awọn ẹgbẹ mimọ l’oke Ni y’o ba Ọ pada. mf Nipa agbara Rẹ, K’a wà k’a kú n’nu Rẹ, cr Gbat’a ba ji l’ọjọ ‘dajọ, f Fi wa si ọtuǹ Rẹ. Amin.