- f Ẹ gbọ́ ìro orin ayọ̀ ọrun,
Orin ayọ̀ ti iṣẹgun Jesu;
Gbogbo ọta l’o tẹri wọn ba fun,
p Ẹṣẹ, ikú, isa-okú pẹlu.
- f O ṣe tan lati lọ gba ijọba,
Fun Baba, Ọlọrun ohun gbogbo;
O ṣe tan lati lọ gbà iyin nla,
T’ o yẹ Olori-ogun ‘gbala wa.
- p Ohun ikanu ni lilọ Rẹ̀, fun
Awọn ayanfẹ ọmọ-ẹhin Rẹ̀.
f Ẹ má ṣe kọnnu l’ ọrọ itunu,
“Emi nlọ pèse àyé nyin silẹ̀”.
- Ọrun gba lọ kuro lẹhin eyi,
Awọsanma se Olugbala mọ;
ff Awọn Ogun-ọrun hó fun ayọ̀,
Fun bibọ̀ Kristi Oluwa ogo.
- mp Ẹ maṣe ba inu nyin jẹ rara,
Jesu, ireti wa, yio tun wa;
f Yio wa mu awọn enia Rẹ̀ lọ,
Sibiti nwọn o ba gbe titilai. Amin.