- f Onigbagbọ, ẹ wá,
Israeli t’ẹmi:
K’ a fi ayọ̀ pejọ,
K’ a gbọhìn didun yi;
ff Jesu goke, O lọ s’ ọrun,
Alufa giga wa r’ ọrun.
- mf Ọjọ etutu de,
Israẹli, ẹ pé:
p A ti ru ẹbọ tan,
Ẹbọ Ọdagutan;
ff Jesu goke, &c.
Ibi mimọ́ julọ,
L’ Olugbala wa lọ,
mp Pẹlu ẹjẹ mimọ́
T’ o ju t’ ewurẹ lọ;
ff Jesu goke, &c.
- ff Kristian, ẹ ho f’ ayọ̀,
Ọlọrun gb’ ẹbọ wa;
cr Jesu mbẹbẹ pupọ,
Bi Alagbawi wa;
Ẹnikẹni t’ o fi ori fun,
ff Y’o ni iyè ainipẹkun. Amin.