Hymn 244: God is gone up on high

Olorun goke lo

  1. f Ọlọrun goke lọ,
    Pẹlu ariwo nla;
    Awọn ipè ọrun
    Nfi ayọ̀ Angẹl hàn;
    ff Gbogbo aiye yọ̀, k’ ẹ gberin,
    Ẹ f’ogo fun Ọba Ogo.

  2. mp O j’ enia laiye,
    f Ọba wa ni lokè;
    Ki gbogbo ilẹ mọ̀
    Ifẹ nla Jesu wa;
    ff Gbogbo aiye, &c.

  3. f Baba fi agbara
    Fun Jesu Oluwa;
    Ogun Angẹl mbọ Ọ,
    On l’Ọba nla ọrun;
    ff Gbogbo aiye, &c.

  4. f L’ or’ itẹ Rẹ̀ mimọ́,
    O gb’ ọpa ododo;
    Gbogbo ọ̀ta Rẹ̀ ni
    Yio ka lọ bẹrẹ.
    ff Gbogbo aiye, &c.

  5. f Ọta Rẹ̀ l’ọta wa,
    Eṣu, aiye, ẹ̀ṣẹ;
    Ṣugbọn y’o r’ẹhin wọn,
    Ijọba Rẹ̀ y’o de.
    ff Gbogbo aiye yọ̀, k’ ẹ gberin,
    Ẹ f’ogo fun Ọba Ogo. Amin.