f Kristi, lẹhin iṣẹgun, Iwọ ti goke lọ; Kerub at’ ogun-ọrun Wá sìn Ọ goke lọ. mf K’aiye sọ ‘tàn na jade— cr Emmanuel wa, f Ti ṣ’ara iy’ ara wa, G’ ori itẹ Baba.
mf Nibẹ l’ o duro, t’ o nsọ di Agbara ẹjẹ Rẹ; O mbẹbẹ fun ẹ̀lẹṣẹ, ‘Wọ Alagbawi wa. p Gbogbo ayidayida T’ ayọ̀, t’ aniyan wa, cr N’ iwọ nṣe iyọ́nu si, T’ iwọ si mbẹbẹ fun.
p Nitori itoye nla Ti agbelebu Rẹ, K’ o fi Ẹmi Rẹ fun wa, Sọ òfo wa d’ère. Titi nipa iyanju, Ọkàn wa o gòke; Lati ba Ọ gbe titi, Li ayọ̀ ailopin. Amin.