- f Alafia f’ ọjọ na, Alleluya !
T’ o pada s’ itẹ lọrun, Alleluya !
p Ọdagutan ẹlẹsẹ, Alleluya !
f Goke ọrun giga lọ. Alleluya !
- ff Iyìn nduro de nibẹ, Alleluya !
Gb’ ori nyin ẹniyin ‘lẹkùn, Alleluya !
Gbà Ọba ogo sile, Alleluya !
Ẹnit’ o ṣẹgun iku. Alleluya !
- f Ọrun gbà Oluwa rẹ̀, Alleluya !
mp Sibẹ , O fẹran aiye, Alleluya !
f B’ o ti pada s’ ọritẹ, Alleluya !
mp O np’ ẹda ni t’On sibẹ. Alleluya !
- mp Wo, O gbọwọ Rẹ̀ soke, Alleluya !
Wo, O f’ apa ifẹ hàn, Alleluya !
Gbọ́, bi On ti nsure fun, Alleluya !
Ijọ Rẹ̀ laiye nihin. Alleluya !
- mf Sibẹ, O mbẹ̀bẹ fun wa, Alleluya !
Iku Rẹ̀ l’ o fi mbẹbẹ, Alleluya !
cr O npèse àye fun wa, Alleluya !
f On l’ akọbi iran wa. Alleluya !
- cr Oluwa,b’a ti gbà Ọ, Alleluya !
Jìna kuro lọdọ wa, Alleluya !
f M’ ọkan wa lọ sibẹ na, Alleluya !
ff K’a wá Ọ lokè ọrun. Alleluya ! Amin.