Hymn 241: See, the Lord ascends in triumph

Wo Asegun b’o ti goke

  1. Wo Aṣẹgun b’o ti gòke,
    Wò Ọba n’nu ọla Rẹ̀,
    O gùn kẹkẹ ofurufu
    Lọ sọrun agbala Rẹ̀;
    Gbọ orin awọn Angẹli,
    Halleluya ni nwọn nkọ,
    Awọn ‘lẹkun si ṣi silẹ,
    Lati gbà Ọba ọrun.

  2. mf Tani Ologo ti mbọ yi,
    T’on ti ipè jubeli?
    p Oluwa awọn ‘mọ-ogun,
    On to ti ṣẹgun fun wa,
    p O jiya lor’ agbelebu,
    O jinde ninu oku,
    f O ṣẹgun Eṣu at’ ẹ̀ṣẹ,
    Ati gbogbo ọta Rẹ̀.

  3. mf B’o ti nbuk’ awọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀,
    A gba kuro lọwọ wọn;
    Bi oju nwọn si ti nwo lọ.
    O nù nin’ awọsanma;
    Ẹnit’o ba Ọlọrun rìn,
    T’o si nwasu otitọ,
    On, Eẹọku wa, l’a gbe lọ
    S’ile Rẹ̀ loke ọrun.

  4. mp On, Aarọn wa, gbé ẹjẹ Rẹ̀
    Wọ̀ inu ikele lọ,
    Jọṣua wa, ti wọ̀ Kenaan,
    Awon oba nwariri;
    mf A fi di ẹya Israel
    Mulẹ nibi simi wọn
    Ẹlija wa si fẹ fun wa
    N ilọpo meji Ẹmi

  5. f Iwọ ti gbe ara wọ̀
    Lọ s` ọw’ ọtun Ọlorun,
    A si joko nibi giga
    Pẹlu Rẹ ninu ogo ;
    ff Awọn Angẹli mbọ jesu,
    Enia joko lor’ itẹ,
    Oluwa, b’ Iwọ ti goke,
    Jọ jẹ k’a le goke bẹ. Amin.